Ninu awon oniranran daada ati awon eko ti o kun

Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe: Ti ile ba ti nsu – tabi ti e ba ti di irole – ki e ya ko awon omo yin ro nibi ki won maa jade, toripe dajudaju awon esu ma nfonka orile nigbanaa, ti wakati kan ba ti wa lo ninu oru, e le wa tu won sile, ki e si ti awon ilekun yin, ki e si se iranti oruko Olohun; toripe dajudaju esu o lee si ilekun kan ti won ti ti, ki e si tun de ori awon kete omi yin, ki e si se iranti oruko Olohun, ki e si bo awon igba yin, ki e si se iranti oruko Olohun, ki baa je wipe ki e kan fi nkankan le e ni ori, ki e si pa awon atupa yin. Ki Olohun bawa se ike ati alubarika fun anabi wa Muhammad, ati awon ara ile re ati awon saabe re lapapo.

API