Adura diduro lori Safa ati Marwa

Nigbati anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – sunmo Safa o ka: Innas sofa wal marwata min sha'aairil laah. Dajudaju Safa ati Marwa ninu awon aaye ami Olohun lo wa. Maa bere pelu ohun ti Olohun bere pelu e. O wa bere pelu Sofa o si gun un titi ti o fi ri ile, o si da oju ko qiblah, o si se Olohun lokan, o si gbe E tobi, o si so pe: Ko si olujosin fun Kankan ayaafi Alloohu nikansoso ko si akegbe fun Un, ti E ni ola nse, ti E sini eyin nse, Oun sini oba ti o ni ikapa lori gbogbo nkan, a nseri pada, a nwa tutuuba, a nse ijosin fun Olohun, a si nfi eyin fun un, Olohun sika adehun Re, O si ran eru Re lowo, O si segun awon Al-A'azaab ni Oun nikan. Leyinna o wa se adua laari re. o so iru eleyi ni eemeta, Al-Hadiith. O tun wa ninu e pe: o si tun se ni Marwa gegebi o se se ni Sofa.

API