Ola ti o nbe fun mima se asalaatu fun anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a -

Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe: Eniti o ba se asalaatu kan fun emi anabi mewa re ni Olohun o fi da pada fun un.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: E ma so saare mi di odun atipe e maa se asalaatu fun mi; toripe dajudaju asalaatun yin o maa bami ni aaye kaye ti e ba wa.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: Ahun eyan ni eniti won daruko mi lodo re ti ko si le se asalaatu fun mi.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: Dajudaju o nbe fun Olohun awon malaika ti won ma nrin orile kaakiri won si ma nmu kiki awon ijomi wa ba mi.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: Ko si enikankan ti yio salaamo simi ayaafi ki Olohun da emi pada simi lara titi maa fi da a lohun salamo re.

API