Adura ti a maa nse fun omokekere nibi irun ti a ba nki si lara
Olohun so o kuro nibi iya saare
Ti o ba si tun so pe: Olohun ba ni se e ni asiwaju nkan ifipamo rere fun awon obi re mejeeji, ati olusipe ti won o gba ipe re, Olohun ba ni fi je ki osuwon awon obi re o kun keke, je ki laada won o po daadaa, ba ni da a po pelu awon enirere ninu awon olugbagbo ododo, ba ni fi si abe itoju anabi Ibrahim, Olohun ba ni so o pelu ike Re kuro ninu iya ina Jaheem, Olohun ba ni jogun ile ti o dara ju ile ti o ti kuro lo fun un, ati araale ti o dara araale re lo, Olohun forijin awon asiwaju wa ti won ti lo ati awon omowere iru wa ti won ti lo ati awon ti won saaju wa pelu igbagbo. A le wi eleyii naa.
Olohun se e ni araawaju ati asiwaju ati esan