Awon adura ti a ba ji lati oju orun
Eyin ti Olohun Oba ni, eniti o ji wa leyin igba ti O pa wa, odo Re si ni akojopo re yio pada si. (1)
........................
(1) Al-Bukhaari pelu Al-Fat'hi, 11/113
Ko si enikankan ti ijosin to si ayaafi Allah nikan, ko si orogun fun un, ti E ni ola nse, ti E eyin nse, oun ni alagbara lori gbogbo nkan, mimo fun Allaah, eyin ti Allaah ni, ko si si eniti ijosin tosi ayafi Allaah,atipe Allaah ni o tobi ju, atipe ko si ogbon ko si agbara ayafi pelu Allaah Oba ti o ga ju ti O si tobi, Olohun Oba mi se aforijin fun mi . (1)
............................
(1) eniti o ba so eleyi, ti o ba se adura won o jepe re fun un, ti o ba wa dide ti o si se aluwaala leyinna ti o wa kirun won o gba irun re, Al-Bukhaari pelu Al-Fat'hi, 3/39, pelu number 1154, ati eyiti o yato si i, atipe gbolohun re ti Ibnu Maajah ni, lo wo: Sahiihu Ibnu Maajah, 2/335
Gbogbo eyin ti Olohun Oba ni eniti o fun mi ni alaafia ni ara mi, ti O si da emi mi pada fun mi, ti O si yonda fun mi lati ranti Re. (1)
........................
(1) At-Tirmidhiy, 5/473. pelu number 3401, ki o si tun wo: Sohiihut Tirmidhiy, 144/3
Dajudaju o nbe nibi dida sanmo ati ile ati iyapa oru ati osan awon ami fun awon oni laakai**Awon ti won sepe won ma nranti Mi ni ori iduro ati ni ori ijoko ati ni ifegbelele won, won si ma nronu nipa dida awon sanmo ati ile, won wa nso pe Ire Oluwa wa, Iwo ko da eleyi lasan, mimo fun O, so wa kuro ninu iya ina**Ire Oluwa wa dajudaju eniti o ba fisi ina niti paapa O ti yepere re, ko si si oluralowo fun awon alabosi**Ire Oluwa wa dajudaju awa gbo olupepe to npepe si igbagbo si Iimooni pe e gba Olohun Oba yin gbo, awa si gbagbo, Ire Oluwa wa fi ori awon ese wa jin wa, bawa pa awon asise wa re, atipe pawa pelu awon eniire**Ire Oluwa wa fun wa ni ohun ti O se adehun fun wa lati odo awon ojise Re, ki o si ma yepere wa ni ojo aliqiyaamo, dajudaju Ire ki yi adehun pada**Olohun Oba won wa dawon loun pe dajudaju Emi ko ni fi ise osise Kankan ninu yin rare ninu okunrin tabi obinrin, apakan yin lara apakan ni, atipe lara awon ti won se hijira ti won si le won jade kuro ninu ile won, ti won fi ara niwon ni oju ona Mi, atipe ti won jagun ti won si pa won, dajudaju Emi yio bawon pa gbogbo asise won re, atipe dajudaju Emi yio fi won si inu ogba idera ti awon akeremodo nsan ni abe won, eyi je esan lati odo Allaah atipe Allaah ni esan ti o dara ju lo wa lodo Re**Ma jeki o tan o je isesi awon ti won nse keferi ni ilu**Igbadun kekere ni, atipe ibuserisi won inu ina jahannama ni, eleyi si buru ni ibusun**Sugbon awon ti won beru Olohun Oba won, awon alujannah ti awon akeremodo nsan ni abe re nbe fun won, won yio maa se gbere nibe, eleyi je nkan ikona alejo lati odo Allaah, atipe ohun ti nbe ni odo Allaah ni o loore ju fun awon eniire**Atipe dajudaju o nbe ninu awon ti a fun ni tira eniti o ni igbagbo pelu Allaah ati ohun ti a sokale fun yin ati ohun ti a sokale fun won ti won si beru Allaah, won o ki nra awon aayah Olohun pelu owo pooku, awon won yi esan won nbe lodo Olohun won, dajudaju Olohun Allaah yara ni isiro**Eyin onigbagba ododo e se ifarada, ki e sit un maa se ifarada ju awon ota lo, ki e si tun duro sinsin, ki e si tun beru Olohun ki e le ba jere)) (1)
...............................
(1) Awon Aayah yi wa lati inu Suuratul Al-Imraan, 190-200, Al-Bukhaari pelu Al-Fat'hi 8/337. pelu number 4569, ati Muslim, 1/530, pelu number 256.