Iranti sise nigbati eeyan ba nseri pada lati irinajo

Yio gbe Olohun tobi ni gbogbo aaye ti o ba ga ni eemeta, leyinna yio wa so pe: Ko si olujosin fun Kankan ayaafi Alloohu nikansoso, ko si akegbe fun Un, ti E ni ola nse, ti E sini eyin nse, Oun si ni Oba ti O ni ikapa lori gbogbo nkan, a nseri pada, a nwa tituuba, a nse ijosin fun Olohun, a si nfi eyin fun un, Olohun sika adehun Re, O si ran eru Re lowo, O si segun awon Al-A'azaab ni Oun nikan.

API