Ohun ti won ma nso nibi ijoko

Lati odo Ibnu Umar – ki Olohun yonu si awon mejeeji – o so pe: Won maa nka fun ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – nibi ijoko kan ni igba ogorun siwaju ki o to dide: Ire Olohun se aforijin fun mi, ki O si gba tuuba mi, dajudaju Ire ni Oba ti maa ngba tuuba ti si maa nfi ori jinni.

API