Adura ti a maa nse siwaju ki ato jeun
Ti enikookan yin ba fe jeun ki o ya sowipe: mo bere pelu oruko Olohun, ti o ba gbagbe ki o wi i ni ibere ki o ya tete so wipe mo be re pelu oruko Olohun ni ibere re ati ni ipari re
Eniti Olohun ba fun ni ounje je ki o yaa so bayii wipe: Olohun ba ni fi ibukun sinu ounje yii, ki O si fun wa ni eyiti o dara ju u lo je, eniti Olohun ba fun ni wara mu ki o yaa so wipe, Olohun bani fi alubarika sinu re ki O si se alekun re fun wa.