Mima fan salamo ka

Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe: Ee le wo Aljannah afi ki e gba Olohun gbo, ee le gba Olohun gba afi ki e nife arayin, ee wa je ki ntoka yin si nkankan ti o je wipe ti e ba se e ee nife arayin, e maa fon salamo ka laarin ara yin.

Nkan meta kan nbe eniti o ba ko o jo niti paapa o ti ko igbagbo jo: I maa se dogba ndogba dori emi re, ati I maa fon salamo ka fun gbogbo aye, ati I maa na ninu kosi.

Lati odo Abdullaah omo Umar – ki Olohun yonu si awon mejeeji - : Dajudaju aarakunrin kan bi anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – leere wipe iru islaamu wo lo fi ndaa ju? O so pe: ki o maa fun awon eeyan ni ounje, ki o si maa salaamo si eniti o ma ati eniti oo mo.

API