Adura ti a maa n se ti aba fe ki irun si oku lara

Olohun ba ni forijin in, ki O si bani ke e, bani se amojukuro fun un, bani pon isokale re sinu saare re le, bani fe iho inu saare re fun un, bani fo o mo pelu omi ati yinyin ati omi ti o tutu, Olohun bani mo on kuro ninu ese gege bi a se maa n mo aso funfun kuro nibi egbin, Olohun bani fi ile to daaju ile re lo ropo fun un ati awon alabagbeere to dara ju aye re lo, ati aya ti o dara ju aya re lo, Olohun bani mu u wo alujanna, ba ni so o kuro nibi iya saare ati iya ina.

Olohun forijin eniti o nsemi ninu wa ati oku wa, ati eniti o wa ati eniti ko lee wa, ati omo kekere inu wa ati agbalagba, ati okunrin inu wa ati obinrin inu wa, Olohun, eniti O ba da emi re si ninu wa, ba ni je ki o maa semi ninu esin Islam, eniti O ba pa ninu wa, ba ni pa a lori ini igbagbo, Olohun ma je ki a padanu esan re, Olohun ma je ki a sonu leyin iku re.

Olohun dajudaju lagbaja omo lagbaja ti wa ni abe aabo Re bayii, o si ti wa ninu iso Re pelu, ba ni so o kuro ninu fitina saare ati iya ina, Iwo ni O ni pipe adehun ati ododo, fi ori jin in ki O si ke e tori pe Iwo ni Alaforijin Onikee.

Olohun eni yi ni erusin re ati omo erubinrin re, o ni bukata si ike re, ko si ohun ti O fe fi iya re se, ti o ba je pe olusedaadaa ni, bani se alekun daadaa re, ti o ba je eniibi, ba ni se amojukoro nibe fun un

API