Adura ti a maa nse leyin ataya ti o gbeyin ki a to salamo

(Ire Oluwa dajudaju emi wa iso pelu Re kuro nibi iya saare ati kuro nibi iya jahanomo ati kuro nibi fitina isemi aiye ati fitina ti iku ati kuro nibi aburu fitna Masiihud-Dajjaal) (1) ......................... (1) Al-Bukhaari, 2/102, pelu number 1377, ati Muslim, 1/412, pelu number 588, atipe gbolohun yi ti Muslim ni.

(Dajudaju emi wa iso kuro nibi iya saaRe atipe mofi e waso kuro nibi fitna Massihud-Dajjaal, atipe emi fi E waso nibi idamu tabi fitna aiye tabi ti iku, Ire Oluwa dajudaju emi waso nibi oun ti o lefa ese ati ohun gbese) (1) ............................... (1) Al-Bukhaari, 1/202, pelu number 832, ati Muslim, 1.412, pelu number 587.

(Ire Oluwa dajudaju emi se abosi, emi ara mi ni abosi ti o po ati pe kosi eniti olese aforijin awon ese ayafi Iwo, atipe fi orijin mi niti aforijin ti odo Re ki O si kemi, dajudaju Ire ni Oba alaforijin onike) (1) ............................ (1) Al-Bukhaari, 8/168, pelu number 834, ati Muslim, 4/2078, pelu number 2705.

(Ire Oluwa fi orijin min ohun ti motise siwaju ati si eyi ati ohun ti mose ni koko ati ohun ti mose ni gbangba ati ohun ti mose ni ase ju, ati ohun ti o mo nipa Re ju emilo Ire ni o maa nti nkan siwaju Ire ni O si maa nti nkan si eyin kosi eniti ijosin to si ayafi Iwo) (1) ......................... (1) Muslim, 1/534, pelu number 771.

(Ire Oluwa ranmi lowo leri iranti Re ati ida ope fun o ati sise ijosin Re daadaa) (1) ........................... (1) Abu Daaud, 2/86, pelu number 1522, ati An-Nasaai, 3/53, pelu number 2302, atipe Al-Albaaniy so pe o ni alaafia ninu tira Sohiihu Abi Daaud, 1/284.

(Ire Oluwa dajudaju emi wa iso pelu Re kuro nibi ahun sise, mosi wa iso pelu Re kuro nibi ojo sise, atipe mo fi E waso kuro nibi didamipada si isemi ti o ti lo ile atipe mofi E waso kuro nibi fitna idamu ile aiye ati iya saare) (1) ............................... (1) Al-Bukhaari pelu Al-Fat'hu, 6/35, pelu number 2822, ati number 6390.

(Ire Oluwa dajudaju emi toro alujana ni odo Re mosi fi E wa iso kuro nibi ina) (1) ............................... (1) Abu Daaud, pelu number 792, ati Ibnu Maajah, pelu number 910, ki o si tun wo: Sohiihu Ibni Maajah, 2/328.

(Ire Oluwa pelu mimo ti o mo koko ati agbara Re lori eda, damisi ti O ba mo pe isemi ni o loore fun miju, ati pe pami ti O ba mo wipe iku ni olooree fun mi ju, Ire Oluwa dajudaju emi ntoro iberu ni odo Re nikoko ati nigbangba mosi ntoro ni odo Re ni asiko iyonu ati asiko ibinu atipe mo ntoro Iwontowonsi ni odo Re nibi ooro ati osi atipe motoro ola tabi idera tikoni tan, atipe mo ntoro itutu oju koni ja ni odo Re atipe mo ntoro iyonu leyin idajo ni odo Re, mo ntoro isemi tutu leyin iku ni odo Re, atipe mo ntoro adun wiwo oju Re, atipe mo ntoro imaa jeran pipade Re lai ni si inira ti o nfara niyan ati laisi idamu ti o nsoninu, Ire Oluwa sewa loso pelu oso Imani atipe sewani olumona emi to nfini mona) (1) ........................... (1) An-Nasaai, 3/54, 55, pelu number 1304, ati Ahmad, 4/364, pelu number 21666, ti Al-Albaaniy si so pe o ni alaafia ninu tira Sohiihun Nisaai, 1/281.

(Ire Oluwa dajudaju, mo ntoro ni owo Re Ire Allah pelu pe dajudaju Ire ni okan soso eniti gbaogbo okan seri pada si odo Re eniti kobimo atipe ti won kobi I, atipe ti enikankan kodabi Re, pe ki o fi ori awon ese mi jin mi dajudaju Iwo ni Oba Alaforijin Onike) (1) ...................................... (1) An-Nisaai lo gbe e jade, 3/52, pelu number 1300 pelu gbolohun re, ati Ahmad, 4/338, pelu number 18974, ti Al-Albaaniy si so pe o ni alaafia ninu tira Sohiihun Nisaai, 1/280.

(Ire Olohun dajudaju emi nbeere lowo Re pelu mimo daju wipe tie ni eyin nse ko si eniti ijosin tosi ayafi Ire nikan soso, ko si orogun fun O, Oba ti ma nse idekun fun ni, Ire ti o ko seda awon sanmo ati ile, Ire Oba ti o ni gbigbongban ati tira oore ti o ga ju, Ire Oba Abemi Ire Oba ti nbe gbere, dajudaju emi nbeere alujanna lowo Re, mo si nfi O wa isora kuro nibi ina) (1) .............................. (1) Awon ti won se tira Sunan ni won gba a wa: Abu Daaud, pelu number 1495, ati At-Tirmidhiy, pelu number 3544, ati Ibnu Maajah, pelu number 3858, ati An-Nasaai, pelu number 1299, ki o si tun wo: Sohiihu Ibni Maajah, 2/329.

(Ire Olohun dajudaju emi nbeere lowo Re pelu wipe mo njeeri wipe ko si eniti ijosin to si ayafi Iwo Oba Aso Oba Ajironukan to je wipe ko bimi won o si bi I, ko si si enikankan ti o se deede Re) (1) .................................... (1) Abu Daaud, 2/62, pelu number 1493, ati At-Tirmidhiy, 5/515, pelu number 3475, ati Ibnu Maajah, 2/1267, pelu number 3857, ati An-Nisaai, pelu number 1300 pelu gbolohun re, ati Ahmad, pelu number 18974, atipe Al-Albaaniy so pe o ni alaafia ninu tira Sohiihun Nasaai, 1/280, ki o si tun wo: Sohiihu Ibni Maajah, 2/329, ati Sohiihut Tirmidhiy, 3/163.

API