Adura bibere irun

(Ire oluwa se igbesina larin mi ati awon ese mi gege bi osese igbesina larin ibuyo orun ati ibuwo orun, ire oluwa fomi mokure ninu awon ese mi gege bi won se man fo aso funfun mokuro ni ibi idoti ire oluwa fomi kuro nibi ese mi pelu yinyin ati omi ati omitutu) (1) ................................ (1) Al-Bukhaariy, 1/181. pelu number 744, ati Muslim, 1/419, pelu number 598.

(Mimo Re Ire Oluwa pelu eyin Re, atipe oruko Re ni ibukun, ati wipe ola Re ga, atipe kosi eniti ijosin tosi yato si Iwo) (1) ..................... (1) Muslim, pelu number 399, ati awon merin ninu awon ti won se tira sunnah: Abu Daaud, pelu number 775, ati At-Tirmidhiy, pelu number 243, ati Ibnu Maajah, pelu number 806, ati An-Nasaai, pelu number 899, ki o si tun wo: Sohiihut Tirmidhiy, 1/77, ati Sohiihu Ibnnu Maajah, 1/135.

(moda oju mi ko eni ti o da sanmo ati ile ni oluse ni okan soso , ni emi mimo atipe emi o se ebo, dajudaju irun mi ati ijosin mi ati isemi mi ati kiku mi ti Olohun Oba agbalaye ni kosi orogun fun Un, atipe eyi ni won pami lase atipe emi wa ni awon musulumi, Ire ni Oluwa ko si eniti ijosin to si ayafi Iwo, Ire ni Oluwa mi, emi ni eru re mo se abosi ara mi atipe mojewo ese mi atipe fi ori ese mi jinmi lapapo, atipe dajudaju kosi eni ti ole fori ese jin yan ayafi Iwo, atipe fimi mona nibi awon iwa ti o daa, ko si eni ti o le fini mona ayafi Iwo, dari awon iwa buburu kuro ni odo mi kio si eni ti ole dari e kuro ni odo mi ayafi Iwo, moje ipe Re ni ajetunje atipe mowa iranlowo Re, atipe gbogbo ore patatpata wa ni owo Re atipe aburu won kin fi i ti si odo Re, atipe emi wa pelu Re ati odo Re, iwo je Onibukun atipe eni ti o ga mowa aforijin Re, mosi tuba losi odo Re Ire Oluwa) (1) ........................ (1) Muslim lo gbe e jade, 1/534, pelu number 771.

(Oluwa Jubril ati Mikail ati Israfill,. Ire ti o da danmo ati ile ti o se olumo nipa ounti o wa nikoko ati ti o han. Ire ni yio se idajo laarin awon eru Re nibi ohun ti won se iyapa enu si fimi mona nibi ohun ti wa fi iyapa enu si ninu otito pelu iyonda Re dajudaju Ire ni o ma nfi eniti o ba wu O mona losi oju ona to to) (1) ............................ (1) Muslim lo gbe e jade, 1/534, pelu number 770.

(Allah ni otobi ju mogbe titobi fun eni ti o tobi atiwipe mimo Olohun Oba ni owo aro ati ni owo asale) (ni eemeta) (mowa iso pelu Allah kuro ni odo shaitaan: kuro nibi fife ategun re ati fife ategun pelu ito ati fifi owo kan Re) (1) .......................... (1) Abu Daaud lo gbe e jade, 1/203, pelu number 764, ati Ibnu Maajah, 1/265, pelu number 807, ati Ahmad, 4/85, pelu number 16739, Suaibu Al-Arnaauut naa si so nibi ti o ti yannana Musnad pe: ((egbawa yi daa pelu ikunlowo egbawa mii)), Abdul Qoodir Al-Arnaauut naa tun so nigbati o nsalaye agbejade egbawa yi ninu tira Al-Kalimut Toyyib ti Ibnu Taimiya, ni number 78, pe: ((o je egbawa to daa pelu ikunlowo awon egbawa mii)), Al-Albaaniy naa so bee ninu tira Sohiihul Kalimit Toyyib, ni number 62, atipe Muslim gbe e jade lati odo Ibnu Umar - ki Olohun yonu si awon mejeeji - pelu ohun ti o jo o, atipe itan kan wa nibe, 1/420, pelu number 601.

(Ire Oluwa ti E ni eyin(1), Iwo ni imole awon sanmo ati ile ati awon ti o wa ninu won, atipe tire ni eyin, Ire ni O mu sanmo ati ile duro ati oun ti o wa ninu won, atipe tire ni eyin, Ire ni Oluwa awon sanmo ati ile ati eniti o wa ninu won] [atipe tire ni eyin, tire ni nini awon sanmo ohun ti o wa ni ati ile ati ohun ti o wa ni inu won] [Atipe tire ni eyin tire ni nini sanmo ati ile ati awon tio wa ninu won] [atipe tire ni eyin, Ire ni eni to ni sanmo ati ile] [atipe tire ni eyin] [Ire ni Oba ododo ati wipe adehun Re ododo ni, atipe oro Re ododo ni ati pe pipade Re ododo ni atiwipe aljana ododo ni atipe ina Re ododo ni atipe awon anabi ododo niwon, atipe anabi wa Muhammed – ki ike ati ola Olohun maa ba a – ododo ni, atipe ojo al'qiyaama ododo ni] [Ire ni mogbafun, atipe Ire ni mogbe ara le, atipe Ire ni mo gbagbo ati pe odo Re ni mo seri okan pada si, atipe pelu oruko Re ni mo fin dojuko ota, atipe odo Re ni mogbe idajo wa atipe odo Re ni mo nseri idajo si, fi ori jinmi gbogbo ohun ti mo se si iwaju ati ohun ti mo se si eyi ati ohun ti mo se ni ipamon ati ohun ti mo se ni gbangba] [atipe Iwo mo nipa re ju mi lo] [Ire ni O ma nti nkan siwaju ati pe, Ire ni O ma nti nkan si eyin, kosi eni ti ijosin tosi ayafi Ire] [Ire ni Oluwa mi kosi eniti ijosin tosi ayafi Iwo] [atipe kosi agbara ati ogbankan ayafi pelu Allah] (2) .............................. (1) Anabi - ki ike ati ola Olohun maa ba a - je eniti o ma nso o nigbati o ba di lati se tahajjud ni oru. (2) Al-Bukhaariy pelu Al-Fat'hu, 3/3, ati 11/116, ati 13/371. 423, 465, pelu number 1120, ati number 6317, ati number 7385, ati number 7442, ati number 7499, ati Muslim leni o se e ni soki pelu iru e, 1/532, pelu number 769.

API