Awon adua leyin ti a ba salamo nibi irun

(Mon toro aforijin lowo Allah (ao wi i ni eemeta) IRe ni Oluwa, IRe ni obba alaafia atipe odo Re ni Alafia tin wa Ire je onibukun Ire Oba toni gbigbongbo ati oore aponle) (1) ................................. (1) Muslim, 1/414, number 591.

(kosi eniti ijosin tosi ayafi Allah nikan kosi orogun fun tire ni ola se. atipe ti e ni eyin se atipe ohun je alagbara lori gbogbo nkan [ao wi i ni eemeta] Ire Oluwa kosi oludena fun nkan ti a ba fumi atipe kosi eni to le fun mi nkan ti Oba dena atipe agbara kole se an fani fun alagbara odo Re ni agbara ti nwa) (1) ......................... (1) Al-Bukhaari, 1/255, pelu number 844, ati Muslim, 1/414, pelu number 593, atipe ohun ti o wa laarin orun mejeeji yen afikun lati odo Al-Bukhaari ni, pelu number 6473.

(Ko si eni ti ijosin tosi ayafi Allaah ni Oun nikan, ko si orogun fun un tie ni ola, ti E si ni eyin nse, Oun si ni alagbara lori gbogbo nkan, ko si ogbon ko si agbara ayafi pelu Allaah, ko si eniti ijosin tosi ayafi Allaah nikan atipe awa ko ni sin elomii yato si I. Ti E ni ike nse, ti E ni ola nse atipe ti E ni eyin to Rewa nse, ko si eniti ijosin to si ayafi Allaah ni eniti a nse afomo Re fun, atipe awon keferi o ba korira bee) (1) ........................... (1) Muslim, 1/415, pelu number 594.

(Mimo Olohun Oba Allah atipe eyin ti Allah nise, atipe Olohun Oba Allah ni otobi ju (ao wi i ni igba metalelogbon) kosi eniti ijosin tosi ayafi Allah, ni ohun nikan kosi orogun fun ti e ni olase atipe ti eni eyin atipe ohun ni alagbara lori gbogbo nkan) (1) ........................... (1) Muslim, 1/418, pelu number 597, o si tun wa ninu re pe: ((eniti o ba so iyen ni ikeyin irun kookan won yio fi ori ese re jin in, koda ko se deede agbayamuyamu okun)).

Mo bere pelu oruko Olohun Ajoke aye Oba Asake orun (So wipe Olohun okan soso ni **Allahu ni Oba ajironukan ** Ko bimo, enikankan ko sibi ** Ko si si afiwe kankan fun Un ninu gbogbo nkan toda) Mo bere pelu oruko Olohun Oba ajoke aye Oba aseke orun (So wipe mowa isora pelu Oba to ni imole asunba nigba ti Oba yoo ** Nibi aburu awon nkan ti O da ** Ati nibi aburu okunkun nigba ti Oba kun biribiri ** Ati nibi awon aburu awon pofopofo nigbati won ba ta nkan sinu koko ** Ati nibi aburu awon onikeeta nigba ti won ba n se keeta) Mo bere pelu oruko Olohun Oba Ajoke aye Oba Asake (So wipe {ire ojise} mo wa isora pelu Olohun Oba to ni awon eeyan ** Oba toje wipe ohun ni Oba toni agbara lori gbogbo awon eeyan patapata ** Oba ti awon eeyan ma njosin fun lododo ni oun nikan ** Nibi aburu shaetan ti eeyan fi ma ngbagbera nibi ti Olohun ** Eleyi ti ma nko royiroyi sinu okan omoniyan ** Ati nibi aburu awon alujoonu ati aburu ti eeyan) leyin irun kookan(1) .................................. (1) Abu Daaud, 2/86, pelu number 1523, ati At-Tirmidhiy, pelu number 2903, ati An-Nasaai, 3/68, pelu number 1335, ki o si tun wo: Sohiihut Tirmidhiy, 2/8, atipe awon Suura meta yi, won maa npe won ni: awon ohun ti a fi nwa iso. wo: Fat'hul Baari, 9/62.

(Olohun Oba Allah ti kosi eni ti ijosin to si ayafi ohun, Oba abemi eniti oduro to eniti odaduro, ki toogbe besini ki sun, tIRe ni gbogbo ohun to beni sanmo ati ile kosi eniti ole sipe ni odo Re ayafi pelu iyonda Re. Oun o si ma wo ohun ti oun be ni iwaju won ati oun to be ni eyin won atipe won koyo kirika nkankan ninu imo Re ayafi pelu ohun ti O ba fe, aga Re fe tayo awon sanmo ati ile, atipe siso awon mejeji koko inira ba A, atipe Oun ni Oba ti O gaju ti O si tobi) leyin irun kookan (1) ............................... (1) Eniti o ba ka a leyin irun kookan ko si nkankan ti o le ma mu u wo aljannah ayafi ki o ku. An-Nasaai ninu tira Amalul Yaomi wal Lailah, pelu number 100, ati Ibnus Sinniy, pelu number 121, atipe Al-Albaaniy so pe o ni alaafia ninu tira Sohiihul Jaamiu, 5/339, ati Silsilatul Ahaadiithis Sohiiha, 2/697, pelu number 972, atipe aayah number 255 ninu Suuratul Baqorah lo wa.

(Kosi eniti ijosin to si ayafi Allaah ni Oun nikan koni orogun, tie ni ola atipe tie ni eyin O ma nda emi si osi ma n pa emi, atipe ohun ni olagbara lori gbogbo nkan) ao so o ni igba mewa)leyin irun magrib ati irun subhi (1) .................................. (1) Al-Tirmidhiy lo gba a wa, 5/515, pelu number 3474, ati Ahmad, 4/227, pelu number 17990, ki o si wo alaye agbejade re ninu tira: Zaadul Miaad 1/300.

(Ire Oluwa dajudaju emi ntoro imo ti osanfani ni odo Re, ati arisiki ti o ma an, ati ise to je atewogba) ao maa sobe leyin igba ti a ba salamo leyin irun asunba (1) ................................ (1) Ibnu Maajah, pelu number 925, ati An-Nasaai ninu tira Amalul Yaomu wal Lailah, pelu number 102, ko si tun wo: Sohiihu Ibni Maajah, 1/152, ati Maj'mahuz Zawaaid 10/111, atipe yio si pada wa pelu number 95.

API