Adua Irun ti a fi ma nsa esa (irun istihara)

Jabri omo Abdulahi – ki Olohun yonu si awon mejeeji – so pe: Ojise Olohun ki – ki ike ati ola Olohun maa ba a – je eniti o ma n kowa ni istihara nibi gbogbo alamori patapata gege bi ose ma nkowa ni surah ninu al-quran, o wa nso pe: (ti enikan ninu yin bagbe lero alamori kan, kio kirun rakat meji laise irun oranyan, leyin naa ki o wa so bai pe: Ire Oluwa, emi nwa sisa esa ni odo Re pelu imo Re, mo si nwa agbara ni odo Re pelu agbara Re, atipe emi ntoro ola Re ti o tobi, tori pe dajudaju Ire ni O ni agbara emi o ni agbara, atipe Ire ni O mo emi o mo, atipe Iwo ni O nimo nipa awon koko, Ire Oluwa ti o ba je wipe Iwo ba mo pe alamori yi (yio wa daruko bukata re), ni o ba ni oore fun mi ninu esin mi ati igbesi aiye mi ati ni igbeyin oro mi tabi akoko re tabi igbeyin re, tabi ti isin tabi ti ojo iwaju re, ki o ya kadara re fun mi atipe ki ose ni irorun fun mi, leyin naa ki o wa fi barika si funmi, Atipe ti o ba mo wipe alamori yi ba je aburu fun mi ninu esin mi tabi igbesi aye mi ati igbeyin alamori mi tabi o so pe – niti isin tabi ojo iwaju mi – ki o ya seri re pada kuro ni odo mi atipe kio kadara ore funmi nibi ti o bawa, leyinna ki O wa fun mi ni itelorun pelu e) (1) Enikeni ti o ba wa esa lati odo adeda koni kabamo, atipe ti osi tun fi oro lo awon eda ti won je muumini to si duro sinsin ninu alamori re, niti paapa Olohun Oba ti o ga ti o ma an so wipe: (Atipe ire anabi maa bawon jiroro nibin almori, atipe ti o ba ti wa pinnu, ki o wa gbarale Allah) (2) .......................................... (1) Al-Bukhaari, 7/162, pelu number 11162. (2) Suuratu Aal Imraan, Aayah: 159.

API