Adura eniti o ba nberu abosi awon alagbara eniyan

Mo pe Iwo Olohun, Oba ti O ni awon sanmo mejeeje, Oba ti O ni aga Al-arashi ti o tobi, je Oluranlowo fun mi lori lagbaja omo lagbaja, ati awon ijo re ninu awon eda ti O da, ki enikankan ninu won ma se yara se mi ni aburu, eni ti o ba wa iranlowo Re yoo leke, eyin Iwo Olohun gbonngbon, atipe ko si enikankan ti ijosin to si ni ododo ayafi Iwo

Olohun ni Oba ti O tobi julo, Olohun ni agbara ju gbogbo eda Re lo patapata, Olohun ni agbara ju ohun ti mo n beru ti mo si n sora fun lo, mo fi Olohun wa iso, Oba ti ko si eniti ijosin to si ni ododo ayafi Oun, Oba Olumu sanmo mejeeje dani, ti ko je ki won subu si ori ile, ayafi pelu iyonda Re, mo fi wa isora kuro nibi aburu eru Re lagbaja ati awon omo ogun re, ati awon olutele re, ati awon ijo re ninu awon alujannu ati eeyan, Olohun je oluranmise kuro nibi aburu won, eyin Re tobi, iranlowo Re biyi, oruko Re ni ibukun, ko si eniti ijosin t osi ni ododo yato si Iwo…. A o wi eleyii ni igba meta

API