Gbigbe Olohun tobi pelu oko kookan nibi lile oko

Yio gbe Olohun tobi ni gbogbo igba ti o ba nju oko kookan ni awon aaye meteeta ti a ti ma nju oko, leyinna yio sun siwaju, yio o duro yio si se adua ni eniti o da oju ko qibla, leniti yio gbe owo re mejeeji soke nibi aaye iju oko alakoko ati eleekeji. Ama nibi aaye iju oko ti o gbeyin yio ju u, yio si gbe Olohun tobi nibi ojo kookan yio si maa lo ko si nii duro nibe.

API