Wiwa aforijin ati ti tuuba

Ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – so pe: Mo fi Olohun bura dajudaju emi maa nwa aforijin Olohun, mo si maa ntuuba losi odo Re ni ojoojumo ni ohun ti o ju igba aadorin lo.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: Mo pe eyin eeyan e tuuba losi odo Olohun toripe dajudaju emi maa ntuuba lo si odo Re ni ojoojumo ni igba ogorun.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: Eniti o ba so pe: Astagfirulloohal aziimal ladhii laa ilaaha illaa uwal ayyul qoyyuum wa atuubu ilaihi, Olohun yio fi ori ese re jin in koda ki o sa kuro loju ogun.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: Asiko ti Olohun ma nsun mo eru Re ju ni aarin gbungbun oru ti o kehin, ti o ba wa ni ikapa lati maa be ninu eniti yio maa ranti Olohun ni asiko yen yan maa be nibe.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: Asiko ti eru ma nsunmo Olohun Oba re julo ni igbati o je eniti o fi ori kanle ki e ya po ni adua.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: Dajudaju a maa nbo ori okan mi, atipe dajudaju emi ma nwa aforijin Olohun ni igba ogorun ni ojoojumo.

API