Ohun ti eniti alamori ti o dun mo ninu tabi ti o korira ba de ba a maa so

Anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – je eniti o ma nso nigbati alamori ti o dun mo on ba de ba a pe: Ope ni fun Olohun Oba ti o se wipe pelu idera Re ni gbogbo daada fi maa npe. Ti alamori ti o korira ba si de ba a yio so pe: Ope ni fun Olohun Oba lori gbogbo isesi.

API