Adura irinajo

Olohun Oba tobi, Olohun Oba tobi, Olohun Oba tobi, Mimo fun eniti o ro eleyi fun wa ti o si je wipe awa o ni ikapa le e lori. Atipe dajudaju awa odo Olohun wa ni a maa seri pada si. Ire Olohun dajudaju awa nbeere lowo Re nibi irin-ajo wa yi daada ati ipaya, ati ninu ise eyiti O yonu si, Ire Olohun se irin-ajo wa yi ni irorun fun wa, sun jijina re mo wa, Ire Olohun, Iwo ni Aladuroti ninu irin-ajo, Iwo si ni Arole lodo awon ara ile, Ire Olohun, dajudaju emi nfi O wa iso kuro nibi idaamudaabo irin-ajo, ati kuro nibi irisi ibanuje, ati apadabo aburu nibi dukia ati ara ile. Ti o ba wa seri pada yio so won yio wa fi kun won pe: A nseri pada, a nwa tutuuba, a nse ijosin fun Olohun, a si nfi eyin fun Un.

API