Ola tin be fun mima se afomo ati mima fi eyin fun Olohun ati mima se laa ilaha illal laah ati mima gbe Olohun tobi

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: Eniti o ba so pe: Subhaanalloohi wa bi amdihi ni igba ogorun ni ojumo kan won a pa gbogbo ese re re koda ko se deede igbi okun.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: Eniti o ba so pe: Laa ilaaha illaal laahu wahdahu laa shariika lahu, lahul mulku, wa lahul amdu, wa uwa ala kulli shaihin qodiir ni eemewa, o da gegebi eniti o tu okun lorun emi meerin ninu omo Anabi Ismaahiil.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: Gbolohun meji kan nbe won fuye lori ahon, won wuwo ninu osuwon, won je ohun ti Oba Ar-Rahmaan nife si: Subhaanalloohi wa bi amdihi subhaanalloohil adhiim.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: Ki n maa wi so pe: Subhaanalloohu, wal amdu lillaah, wa laa ilaaha ilaal laahu, wallaahu akbar o je nkan ti mo nife si ju gbogbo nkan ti oorun nyo le lori lo.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: Nje enikookan yin le kagara lati ko oro daada egberun ni ojoojumo. Ni onibeere kan ba bi i leere ninu awon ti won joko ti i : bawo ni enikookan wa sele ko oro daada egberun? O sope: yio ma se afomo ni nigba ogorun, won o si ko daada egberun fun un tabi ki won pa ese egberun re fun un.

Eniti o ba so pe: Subhaanalloohil adhiim wa bi amdihi won o gbin igi ope kan fun un ninu aljannah.

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: Ire Abdullaah omo Qois! O o wa je ki ntoka re si pepe oro kan ninu awon pepe oro aljannah? Mo si so pe: mo fe bee ire ojise Olohun, o so pe: so pe: : La aola wala quwwata illa billah

O tun so – ki ike ati ola Olohun maa ba a – pe: Gbolohun ti Olohun Oba nife si ju meerin ni: Subhaanalloohu, wal amdu lillaah, wa laa ilaaha illaal laah, wal loohu akbar, ko si inira nibi ki o bere pelu eyikeyi ti o ba wu o ninu e.

Larubawa oko kan wa ba ojise Olohun – ki ike ati ola Olohun maa ba a – o si so pe: ko mi ni gbolohun kan ti maa ma wi i. o so pe: so pe: Laa ilaaha illal laah wahdahu la shariika lahu, Allaahu akbar kabiira, wal amdu lillaahi kathiira, subhaanalloohi robbil aalamiin, laa aola wa laa quwwata illa bil laahil aziizil akiim, o so pe: gbogbo eleyi ti Oba mi ni, ewo wa ni ti temi? O so pe: so pe: Allaahummo igfirli, war'amni, wahdini, war'zukni.

Ti enikan ba gba Islaam, anabi – ki ike ati ola Olohun maa ba a – maa ko o ni irun kiki, leyinna yio tun wa pa a lase ki o maa se adua pelu awon gbolohun wonyi: Ire Olohun fi ori jin mi, si kemi, si fimi mona, si se alaafia fun mi, si pese ijeemu fun mi.

Dajudaju eyiti o fi nlola ju ninu adua ni: Alhamdulillaah, atipe eyiti o fi nlola ju ninu iranti ni: Laa ilaaha illaal laah.

Nkan ti nje Al-Baaqiyaatus-Soolihaatu ni: Subhaanallooh, wal amdu lillaah, wa laa ilaaha illaal laahu, walloohu akbar, wala aola wala quwwata illaa billaah.

API